Numbers 2:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, Àgọ́ Ẹ̀rí yóo ṣí, pẹlu àgọ́ àwọn ọmọ Lefi. Bí wọ́n ti pàgọ́ yí Àgọ́ náà ká, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe máa ṣí, olukuluku ní ipò rẹ̀, pẹlu àsíá ẹ̀yà rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni agọ́ ajọ yio si ṣí, pẹlu ibudó, awọn ọmọ Lefi lãrin ibudó: bi nwọn ti dó bẹ̃ni nwọn o ṣí, olukuluku ni ipò rẹ̀, pẹlu ọpagun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni àwọn ọmọ Léfì Àti Àgọ́ ìpàdé yóò tẹ̀ṣíwájú láàrin ibùdó àwọn ènìyàn, wọn yóò tẹ̀ṣíwájú ní ṣíṣẹ̀ n tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe pa ibùdó, olúkúlùkù láàyè rẹ̀, àti lábẹ́ ọ̀págun rẹ̀.