Numbers 2:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àsíá ibùdó ẹ̀yà Efuraimu yóo máa wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ní ìsọ̀rí-ìsọrí; Eliṣama ọmọ Amihudu ni yóo jẹ́ olórí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni ìha ìwọ-õrùn ni ki ọpagun ibudó Efraimu ki o wà gẹgẹ bi ogun wọn: Eliṣama ọmọ Ammihudu yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Efraimu:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìhà ìlà oòrùn ni ìpín Éfúráímù yóò pa ibùdó rẹ̀ sí lábẹ́ ọ́págun rẹ̀. Olórí Éfúráímù ni Élíṣámà ọmọ Ámíhúdì.