Numbers 2:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ọmọ Israẹli tí a kà, gẹ́gẹ́ bí ìdílé baba wọn. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àgọ́ tí a kà ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹtadinlogun ati aadọjọ (603,550).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eyi li awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ile baba wọn: gbogbo awọn ti a kà ni ibudó gẹgẹ bi ogun wọn, jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ o le egbejidilogun din ãdọta.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n kà nípa ìdílé wọn. Gbogbo àwọn tó wà ní ibùdó, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́-ó-lé-egbéjìdínlógún-dín àádọ́ta (603,550).