Numbers 2:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ibùdó Juda jẹ́ ẹgbaa mẹtalelaadọrun-un ó lé irinwo (186,400). Àwọn ni yóo máa ṣáájú nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ kó kúrò ní ibùdó kan lọ sí ibòmíràn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Juda jẹ́ ẹgba mẹtalelãdọrun o le irinwo, gẹgẹ bi ogun wọn. Awọn yi ni yio kọ́ ṣí.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn tí a yàn sí ibùdó Júdà, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́taléláàdọ́rin ó lé irínwó (186,400). Àwọn ni yóò kọ́kọ́ ṣáájú.