Numbers 20:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn ará Edomu dáhùn pé, “A kò ní jẹ́ kí ẹ gba ilẹ̀ wa kọjá, bí ẹ bá sì fẹ́ kọjá pẹlu agídí, a óo ba yín jagun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Edomu si wi fun u pe, Iwọ ki yio kọja lọdọ mi, ki emi ki o má ba jade si ọ ti emi ti idà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Édómù dáhùn pé: “Ẹ̀yin kò le gba ibí kọjá; bí ẹ bá dán an wò, a ó dìde ogun síyín a ó sì bá yín jà pẹ̀lú idà.”