Numbers 20:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli ní, “Ojú ọ̀nà ni a óo máa tọ̀, bí àwa tabi ẹran wa bá tilẹ̀ mu omi yín, a óo sanwó rẹ̀. Ohun kan tí a sá fẹ́ ni pé kí ẹ jẹ́ kí á kọjá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Israeli si wi fun u pe, Ọ̀na opópo ọba li awa o gbà: bi awa ba mu ninu omi rẹ, emi ati ẹran mi, njẹ emi o san owo rẹ̀: laiṣe ohun miran, ki nsá fi ẹsẹ̀ mi là ilẹ kọja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dáhùn pé: “A ó gba ọ̀nà tóóró, bí àwa tàbí ẹran ọ̀sìn wa bá sì mú lára omi rẹ, a ó san owó rẹ̀. A kàn fẹ́ rìn kọjá lórí ilẹ̀ rẹ ni kò sí nǹkankan mìíràn tí a fẹ́ ṣe.”