Numbers 21:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n tún ṣí kúrò ní àfonífojì Seredi, wọ́n pa àgọ́ wọn sí òdìkejì odò Arinoni, tí ó wà ní aṣálẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ láti agbègbè àwọn ará Amori. Odò Arinoni jẹ́ ààlà ilẹ̀ Moabu, ó wà láàrin ilẹ̀ Moabu ati ilẹ̀ Amori.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati ibẹ̀ lọ nwọn ṣí, nwọn si dó si ìha keji Arnoni, ti mbẹ li aginjù, ti o ti àgbegbe awọn ọmọ Amori wá: nitoripe Arnoni ni ipinlẹ Moabu, lãrin Moabu ati awọn Amori.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n gbéra kúrò níbẹ̀ wọ́n sì pa ibùdó sí ẹ̀bá ọ̀nà Ánónì, tí ó wà ní Ìfà-gùn ihà tó kángun sí ibi tí ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámórì wa. Ánónì jẹ́ ààlà fún ilẹ̀ Móábù, láàrin Móábù àti Ámórì.