Numbers 21:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli pa pupọ ninu wọn, wọ́n gba ilẹ̀ wọn láti odò Arinoni lọ dé odò Jaboku títí dé ààlà àwọn ará Amoni. Wọn kò gba ilẹ̀ àwọn ará Amoni nítorí pé wọ́n jẹ́ alágbára.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Israeli si fi oju idà kọlù u, o si gbà ilẹ rẹ̀ lati Arnoni lọ dé Jaboku, ani dé ti awọn ọmọ Ammoni; nitoripe ipinlẹ ti awọn ọmọ Ammoni lí agbara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àmọ́ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, wọn fi ojú idà pa wọ́n, wọ́n sì gba ilẹ̀ láti ọwọ́ Ánónì lọ dé Jábókù, títí tí ó fi dé ilẹ̀ àwọn ará Ámónì, nítorí pé ààlà wọn jẹ́ olódi.