Numbers 21:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA gbọ́ ohùn àwọn ọmọ Israẹli, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣẹgun àwọn ará Kenaani. Wọ́n run àwọn ati àwọn ìlú wọn patapata. Àwọn ọmọ Israẹli sì sọ ibẹ̀ ní Horima.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si gbọ́ ohùn Israeli, o si fi awọn ara Kenaani tọrẹ, nwọn si run wọn patapata, ati ilu wọn: o si sọ orukọ ibẹ̀ na ni Horma.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì fi àwọn ará Kénánì lé wọn lọ́wọ́. Wọ́n pa wọ́n run pátapáta; torí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ ní Hómà.