Numbers 21:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣí, wọ́n gba ọ̀nà Baṣani. Ogu ọba Baṣani sì bá wọn jagun ní Edirei.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si yipada, nwọn si gòke lọ li ọ̀na Baṣani: Ogu ọba Baṣani si jade tọ̀ wọn lọ, on, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, si ogun ni Edrei.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà wọ́n pẹ̀yìn dà wọ́n sì gòkè lọ sí Básánì, Ógì ọba ti Básánì àti gbogbo àwọn ọmọ ogun tí ó wọ́de ogun jáde lati pàdé wọn ní ojú ogun ní Édírélì.