Numbers 21:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun ati Mose, wọ́n ní, “Kí ló dé tí ẹ fi kó wa wá láti Ijipti, pé kí á wá kú ninu aṣálẹ̀ yìí? Kò sí oúnjẹ, kò sí omi, burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ yìí ti sú wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn enia na si bá Ọlọrun, ati Mose sọ̀ pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke lati Egipti jade wá lati kú li aginjù? nitoripe àkara kò sí, bẹ̃ni kò sí omi; onjẹ futẹfutẹ yi si sú ọkàn wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí OLÚWA àti Mósè, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde láti Éjíbítì kí a ba le wá kú sí ihà yìí? Kò sí oúnjẹ! Kò sì sí omi! Àwa sì kóríra oúnjẹ tí kò dára yìí!”