Numbers 21:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n bá wá sọ́dọ̀ Mose, wọ́n ní, “A ti ṣẹ̀ nítorí tí a ti sọ̀rọ̀ òdì sí OLUWA ati sí ọ. Gbadura sí OLUWA kí ó mú ejò wọnyi kúrò lọ́dọ̀ wa.” Mose bá gbadura fún àwọn eniyan náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina li awọn enia na ṣe tọ̀ Mose wá, nwọn si wipe, Awa ti ṣẹ̀, nitoriti awa ti bá OLUWA ati iwọ sọ̀; gbadura si OLUWA ki o mú ejò wọnyi kuro lọdọ wa. Mose si gbadura fun awọn enia na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn sì wá sí ọ̀dọ̀ Mósè wọn wí pé, “A ti dá ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí a sọ̀rọ̀ òdì sí OLÚWA àti sí ìwọ pẹ̀lú. Gba àdúrà pé kí OLÚWA mú ejò náà kúrò lọ́dọ̀ wa.” Nígbà náà ni Mósè gbàdúrà fún àwọn ènìyàn.