Numbers 22:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Balaamu dá àwọn oníṣẹ́ Balaki lóhùn pé, “Balaki ìbáà fún mi ní ààfin rẹ̀, kí ààfin náà sì kún fún fadaka ati wúrà, n kò ní lòdì sí àṣẹ OLUWA Ọlọrun mi, ninu nǹkan kékeré tabi nǹkan ńlá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Balaamu si dahùn o si wi fun awọn iranṣẹ Balaki pe, Balaki iba fẹ́ fun mi ni ile rẹ̀ ti o kún fun fadaká ati wurà, emi kò le rekọja ọ̀rọ OLUWA Ọlọrun mi, lati ṣe ohun kekere tabi nla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Bálámù dá wọn lóhùn pé, “Kó dà tí Bálákì bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, n kò ṣe ohunkóhun tí ó tóbi tàbí kéré tí o kọjá òfin OLÚWA Ọlọ́run mi.