Numbers 22:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí angẹli tí ó dúró ní ọ̀nà pẹlu idà ní ọwọ́ rẹ̀, ó yà kúrò ní ojú ọ̀nà sinu igbó. Balaamu lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà láti darí rẹ̀ sójú ọ̀nà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kẹtẹkẹtẹ na si ri angeli OLUWA duro loju ọ̀na, idà rẹ̀ fifàyọ si wà li ọwọ́ rẹ̀: kẹtẹkẹtẹ na si yà kuro loju ọ̀na, o si wọ̀ inu igbẹ́: Balaamu si lù kẹtẹkẹtẹ na, lati darí rẹ̀ soju ọ̀na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sì rí áńgẹ́lì OLÚWA tí ó dúró ní ojú ọ̀nà pẹ̀lú idà tí a fà yọ ní ọwọ́ rẹ̀, ó kọjú kúrò ní ọ̀nà lọ sínú oko. Bálámù sì lù ú pé kí ó gbé òhun padà lọ sí ojú ọ̀nà.