Numbers 22:34 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Balaamu dá angẹli náà lóhùn pé, “Mo ti dẹ́ṣẹ̀, n kò sì mọ̀ pé o dúró lójú ọ̀nà láti dínà fún mi. Ó dára, bí o kò bá fẹ́ kí n lọ, n óo pada.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Balaamu si wi fun angeli OLUWA pe, Emi ti ṣẹ̀; nitori emi kò mọ̀ pe iwọ duro dè mi li ọ̀na; njẹ bi kò ba ṣe didùn inu rẹ, emi o pada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bálámù sọ fún ángẹ́lì OLÚWA pé, “Mo ti dẹ́ṣẹ̀, èmi kò mọ̀ pé o dúró níwájú ọ̀nà láti dojú kọ mí, Nísinsin yìí tí inú rẹ kò bá dùn, èmi ó padà.”