Numbers 23:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ta ló lè ka àwọn ọmọ Jakọbu tí ó pọ̀ bí iyanrìn? Tabi kí ó ka idamẹrin àwọn ọmọ Israẹli? Jẹ́ kí n kú ikú olódodo, kí ìgbẹ̀yìn mi sì dàbí tirẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tali o le kà erupẹ Jakobu, ati iye idamẹrin Israeli? Jẹ ki emi ki o kú ikú olododo, ki igbẹhin mi ki o si dabi tirẹ̀!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ta ni ó lè ka eruku Jákọ́bù tàbí ka ìdámẹ́rin Ísírẹ́lì? Jẹ́ kí èmi kú ikú olóòtọ́, kí ìgbẹ̀yìn mi kí ó dàbí ti wọn!”