Numbers 23:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Balaki sọ fún Balaamu pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn. Apákan wọn ni o óo rí, o kò ní rí gbogbo wọn, níbẹ̀ ni o óo ti bá mi ṣépè lé wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Balaki si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bá mi lọ si ibomiran, lati ibiti iwọ o le ri wọn; kìki apakan wọn ni iwọ o ri, iwọ ki yio si ri gbogbo wọn tán; ki o si fi wọn bú fun mi lati ibẹ̀ lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà Bálákì sọ fún un pé, “Wá pẹ̀lú mi sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn; wà á rí díẹ̀ Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn. Láti ibẹ̀, wá fi wọ́n bú fún mi.”