Numbers 23:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó pada dé ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti ẹbọ sísun náà, Balaki sì bèèrè ohun tí OLUWA sọ lọ́wọ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si tọ̀ ọ wá, kiyesi i, o duro tì ẹbọ sisun rẹ̀, ati awọn ijoye Moabu pẹlu rẹ̀. Balaki si bi i pe, Kini OLUWA sọ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì báà tí ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Móábù. Bálákì sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni OLÚWA wí?”