Numbers 24:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Balaamu rí i pé OLUWA ń súre fún àwọn ọmọ Israẹli, kò lọ bíi ti iṣaaju láti bá OLUWA pàdé. Ṣugbọn ó kọjú sí aṣálẹ̀,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NIGBATI Balaamu ri pe o wù OLUWA lati bukún Israeli, on kò lọ mọ́ bi ìgba iṣaju, lati wá ìfaiya, ṣugbọn o doju rẹ̀ kọ aginjù.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìnyìí nígbà tí Bálámù rí i wí pé ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn láti bùkún àwọn Ísírẹ́lì, kò lo ọ̀nà ìṣoṣó gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ó yí ojú rẹ̀ sí apá ihà.