Numbers 24:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo wo ọjọ́ iwájú rẹ, mo sì rí ẹ̀yìn ọ̀la rẹ. Ìràwọ̀ kan yóo jáde wá láàrin àwọn ọmọ Jakọbu, ọ̀pá àṣẹ yóo ti ààrin àwọn ọmọ Israẹli jáde wá; yóo run àwọn àgbààgbà Moabu, yóo sì wó àwọn ará Seti palẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi ri i, ṣugbọn ki iṣe nisisiyi: emi si wò o, ṣugbọn kò sunmọtosi: irawọ kan yio ti inu Jakobu jade wá, ọpa-alade kan yio si ti inu Israeli dide, yio si kọlù awọn igun Moabu, yio si ṣẹ́ gbogbo awọn ọmọ irọkẹ̀kẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Mo rí i, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìsinsin yìí, Mo kíyèsi, ṣùgbọ́n kò súnmọ́. Ìràwọ̀ kan yóò jáde láti ọ̀dọ̀ Jákọ́bù; yóò yọ jáde láti Ísírẹ́lì. Yóò tẹ̀ fọ́ orí Móábù, yóò sì fọ́ agbárí gbogbo ọmọ Ṣéétì.