Numbers 24:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọlọrun kó wọn ti Ijipti wá, ó jà fún wọn gẹ́gẹ́ bí àgbáǹréré. Wọn yóo pa àwọn ọ̀tá wọn run, wọn óo wó egungun wọn, wọn óo sì fi ọfà pa wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọlọrun mú u lati Egipti jade wá; o ní agbara bi ti agbanrere: on o jẹ awọn orilẹ-ède ti iṣe ọtá rẹ̀ run, yio si fọ́ egungun wọn, yio si fi ọfà rẹ̀ ta wọn li atapoyọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọlọ́run mú wọn jáde láti Éjíbítì wá; wọ́n ní agbára gẹ́gẹ́ bí i ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọ́n jẹ orílẹ̀ èdè run, wọ́n fọ́ egungun wọn sí wẹ́wẹ́; wọ́n fi idà wọn gún wọn.