Numbers 25:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“N kò ní bínú sí Israẹli mọ nítorí ohun tí Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, alufaa, ṣe. Ó kọ̀ láti gba ìbọ̀rìṣà láàyè, nítorí náà ni n kò ṣe ní fi ibinu pa àwọn ọmọ Israẹli run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni alufa ti yi ibinu mi pada kuro lara awọn ọmọ Israeli, nipa itara rẹ̀ nitori mi lãrin wọn, ki emi ki o máṣe run awọn ọmọ Israeli ninu owú mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Fínéhásì ọmọ Élíásárì ọmọ Árónì, àlùfáà, ti yí ìbinú mi padà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì: nítorí tí ó ní ìtara bí èmi náà ti ní ìtara fún iyì mi láàrin wọn, kí ó lè jẹ́ pé èmi ló pa wọ́n run nínú ìtara mi sí wọn.