Numbers 25:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Majẹmu náà ni pé mo ti yan òun ati arọmọdọmọ rẹ̀ láti máa ṣe alufaa ní Israẹli títí lae nítorí pé ó ní ìtara fún Ọlọrun rẹ̀, ó sì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan Israẹli.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio jẹ́ tirẹ̀ ati ti irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀, ani majẹmu iṣẹ-alufa titi-aiye; nitoriti o ṣe itara fun Ọlọrun rẹ̀, o si ṣètutu fun awọn ọmọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun àti irú ọmọ rẹ̀ yóò ní májẹ̀mú láéláé fún iṣẹ́ àlùfáà, nítorí pé ó ní ìtara fún Ọlọ́run rẹ̀ láti fi yẹ́ Ọlọ́run sí, ó sì ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”