Numbers 25:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
nítorí ibi tí wọ́n ṣe, ati títàn tí wọ́n tàn yín ní Peori, ati nítorí ọ̀rọ̀ Kosibi, ọmọ baálé kan ní ilẹ̀ Midiani, arabinrin wọn, tí a pa nígbà àjàkálẹ̀ àrùn ti Peori.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti nwọn fi ẹ̀tan wọn yọ nyin lẹnu, eyiti nwọn tàn nyin niti ọ̀ran Peori, ati niti ọ̀ran Kosbi, ọmọ ijoye Midiani kan, arabinrin wọn, ẹniti a pa li ọjọ́ àrun nì niti ọ̀ran Peori.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nítorí pé wọ́n ṣe sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀ta nígbà tí wọ́n tàn yín nípa ìṣẹ̀lẹ̀ Péórì, àti arábìnrin wọn Kósíbì ọmọbìnrin ìjòyè Mídíánì kan, obìnrin tí a pa nígbà tí àjàkálẹ̀-àrùn ṣẹlẹ̀ nítorí Péórì.