Numbers 25:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Mú gbogbo àwọn olórí Israẹli, kí o so wọ́n kọ́ sórí igi ninu oòrùn títí tí wọn óo fi kú níwájú OLUWA. Nígbà náà ni n kò tó ni bínú sí àwọn eniyan náà mọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si sọ fun Mose pe, Mú gbogbo awọn olori awọn enia na, ki o si so wọn rọ̀ si õrùn niwaju OLUWA, ki imuna ibinu OLUWA ki o le yipada kuro lọdọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sọ fún Mósè pé; “Mú gbogbo àwọn olórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, pa wọ́n kí o sì fi wọ́n kọ́ sórí igi ní gbangba nínú oòrùn níwájú OLÚWA, kí ìbínú OLÚWA lè kúrò ní ọ̀dọ̀ Ísírẹ́lì.”