Numbers 26:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ ka iye àwọn eniyan náà láti ẹni ogún ọdún lọ sókè,” gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti nìwọ̀nyí:
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ kà iye awọn enia na, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, ati fun awọn ọmọ Israeli, ti o ti ilẹ Egipti jade wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ka iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ ogun (20) ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti paláṣẹ fún Mósè.” Èyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó jáde láti Éjíbítì wá: