Numbers 26:62 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àwọn ọmọkunrin tí a kà ninu ẹ̀yà Lefi láti ẹni oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé ẹgbẹrun (23,000). Wọn kò kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli nítorí pé wọn kò ní ilẹ̀ ìní ní Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mọkanla o le ẹgbẹrun, gbogbo awọn ọkunrin lati ọmọ oṣù kan ati jù bẹ̃ lọ: nitoripe a kò kà wọn kún awọn ọmọ Israeli, nitoriti a kò fi ilẹ-iní fun wọn ninu awọn ọmọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Léfì láti oṣù kan àti ju bẹ́ẹ̀ lọ ẹgbàá mọ́kànlá ó lé lẹ́gbẹ̀rún (23,000). Wọn kò ka wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tókù nítorí tí wọ́n kò gba ogún ìní lára wọn.