Numbers 26:63 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àwọn tí Mose ati Eleasari kà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá Jọdani létí Jẹriko nìwọ̀nyí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi li awọn ti a kà lati ọwọ́ Mose ati Eleasari alufa wá, awọn ẹniti o kà awọn ọmọ Israeli ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn wọ̀nyí ni Mósè àti Élíásárì àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lẹ́bá odò Jọ́dánì létí Jẹ́ríkò.