Numbers 26:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Eliabu bí Nemueli, Datani ati Abiramu. Datani ati Abiramu yìí ni wọ́n jẹ́ olókìkí eniyan láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ni wọ́n bá Mose ati Aaroni ṣe gbolohun asọ̀ nígbà tí Kora dìtẹ̀, tí wọ́n tako OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn ọmọ Eliabu; Nemueli, ati Datani, ati Abiramu. Eyi ni Datani ati Abiramu na, ti nwọn lí okiki ninu ijọ, ti nwọn bá Mose ati Aaroni jà ninu ẹgbẹ Kora, nigbati nwọn bá OLUWA jà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
àwọn ọmọkùnrin Élíábù ni Némúélì àti Dátanì àti Ábírámù. Èyí ni Dátanì àti Ábírámù náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mósè àti Árónì tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kórà nígbà tí wọ́n bá OLÚWA jà.