Numbers 27:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
nítorí o ṣàìgbọràn sí àṣẹ mi ninu aṣálẹ̀ Sini. Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń kùn sí mi ní Meriba, ẹ kọ̀ láti fi títóbi agbára mi hàn níwájú àwọn eniyan náà.” (Meriba ni wọ́n ń pe àwọn omi tí ó wà ní Kadeṣi ní aṣálẹ̀ Sini).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ mi li aginjù Sini, ni ìja ijọ, lati yà mi simimọ́ ni ibi omi nì niwaju wọn. (Wọnyi li omi Meriba ni Kadeṣi li aginjù Sini.)
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nítórí nígbà tí ìlú ṣọ̀tẹ̀ níbi omi ní Aginjù Ṣínì, tí gbogbo yín se àìgbọ́ràn sí mi láti yà mí sí mímọ́ níwájú wọn.” (Èyí ni omi Méríbà ní Kádésì ní ihà Sínì.)