Numbers 27:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Baba wa kú sinu aṣálẹ̀ láìní ọmọkunrin kankan. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kora tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí OLÚWA, ṣugbọn ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀ ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Baba wa kú li aginjù, on kò si sí ninu ẹgbẹ awọn ti o kó ara wọn jọ pọ̀ si OLUWA ninu ẹgbẹ Kora: ṣugbọn o kú ninu ẹ̀ṣẹ ara rẹ̀; kò si lí ọmọkunrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Baba wa kú sí ihà. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kórà tí wọ́n kó ara wọn pọ̀ lòdì sí OLÚWA, Ṣùgbọ́n ó kú nítórí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì fi ọmọkùnrin sílẹ̀.