Numbers 28:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Fún ẹbọ ohun jíjẹ, ẹ lo ìdámẹ́wàá mẹta ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa, tí a fi òróró pò fún akọ mààlúù kan ati idamẹrin ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa tí a fi òróró pò fún àgbò kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati idamẹwa mẹta òṣuwọn iyẹfun, ti a fi oróro pò, fun akọmalu kan, fun ẹbọ ohunjijẹ; ati idamẹwa meji òṣuwọn iyẹfun, ti a fi oróro pò, fun àgbo kan, fun ẹbọ ohunjijẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí wọn ó rú ẹbọ ohun jíjẹ ẹbọ ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun tí a pòpọ̀ pẹ̀lú òróró; pẹ̀lú àgbò, ni kí wọn ó rú ẹbọ ohun jíjẹ tí í ṣe ìdáméjì nínú mẹ́wá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a pòpọ̀ mọ́ òróró;