Numbers 28:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí ẹbọ ohun mímu jẹ́ ààbọ̀ òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún akọ mààlúù kan, ìdámẹ́ta òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún àgbò kan ati idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún ọ̀dọ́ aguntan kan. Èyí ni ìlànà ẹbọ sísun ti ìbẹ̀rẹ̀ oṣù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹbọ ohunmimu wọn ki o jẹ́ àbọ òṣuwọn hini ti ọti-waini fun akọmalu kan, ati idamẹta òṣuwọn hini fun àgbo kan, ati idamẹrin òṣuwọn hini fun ọdọ-agutan kan: eyi li ẹbọ sisun oṣuṣù ni gbogbo oṣù ọdún.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ẹbọ ohun mímu wọn jẹ́ ààbọ̀ òṣùwọ̀n hínì ti ọtí wáìnì, fún akọ màlúù kan, àti ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n hínì fún àgbò kan àti ìdámẹ́rin òṣùwọ̀n hínì fún ọ̀dọ́ àgùntàn kan. Èyí ni ẹbọ sísun tí wọn ó máa rú ní oṣù kọ̀ọ̀kan nínú ọdún.