Numbers 28:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí ẹ máa fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù meji, ati àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí wọn kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ki ẹnyin ki o ru ẹbọ kan ti a fi iná ṣe, ẹbọ sisun si OLUWA; ẹgbọrọ akọmalu meji, ati àgbo kan, ati akọ ọdọ-agutan meje ọlọdun kan: ki nwọn ki o jẹ́ alailabùku fun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ rú ẹbọ àfinásun sí OLÚWA, ẹ rú u pẹ̀lú ọ̀dọ́ màlúù méjì akọ, ẹbọ sísun pẹ̀lú iná àgbò kan àti ọ̀dọ́ àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kí wọn kí ó jẹ́ aláìlábùkù.