Numbers 28:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ati ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kan,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹbọ ohunjijẹ wọn iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn ni ki ẹnyin ki o múwa fun akọmalu kan, ati idamẹwa meji òṣuwọn fun àgbo na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí ẹ pèsè ẹbọ ohun mímu pẹ̀lú ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò; pẹ̀lú àgbò, ìdá méjì nínú mẹ́wàá;