Numbers 29:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ti ọjọ́ kinni oṣù, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ pẹlu ẹbọ ohun mímu ojoojumọ, gẹ́gẹ́ bí ìlànà wọn. Wọ́n jẹ́ ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlu ẹbọ sisun oṣù, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn, gẹgẹ bi ìlana wọn, fun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú ẹbọ sísun oṣù àti ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ẹbọ mímu wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà wọn. Fún òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe sí OLÚWA.