Numbers 3:38 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mose pẹlu Aaroni ati àwọn ọmọ wọn yóo pa àgọ́ tiwọn sí ìhà ìlà oòrùn, níwájú Àgọ́ Àjọ. Àwọn ni yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Israẹli ní ibi mímọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ibi mímọ́, pípa ni kí wọ́n pa á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn ti o pagọ́ niwaju agọ́ na, si ìha ìla-õrùn, ani niwaju agọ́ ajọ si ìha ìla-õrùn ni, ki o jẹ́ Mose, ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ti nwọn nṣe itọju ibi-mimọ́, fun itọju awọn ọmọ Israeli; alejò ti o ba si sunmọtosi pipa li a o pa a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè àti Árónì pẹ̀lú àwọn ọmọ yóò pa àgọ́ ní ìdojúkọ ìwọ̀ oòrùn níwájú Àgọ́ Ìpàdé. Iṣẹ́ wọn ni láti máa mójútó iṣẹ́ ìsìn ibi mímọ́ àti láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ẹnikẹ́ni tó bá súnmọ́ ibi mímọ́ yàtọ̀ sí àwọn tí a yàn, pípa ni kí ẹ pa á.