Numbers 3:39 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àwọn ọmọ Lefi lọkunrin, láti ọmọ oṣù kan sókè tí Mose kà ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA jẹ́ ẹgbaa mọkanla (22,000).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Lefi, ti Mose ati Aaroni kà nipa aṣẹ OLUWA, gẹgẹ bi idile wọn, gbogbo awọn ọkunrin lati ọmọ oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, nwọn jẹ́ ẹgba mọkanla,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Léfì tí a kà gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pa á láṣẹ fún Mósè àti Árónì gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, pẹ̀lú gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlá (22,000).