Numbers 3:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nadabu ati Abihu kú nígbà tí wọ́n fi iná tí a kò yà sí mímọ́ rúbọ sí OLUWA ninu aṣálẹ̀ Sinai. Wọn kò bímọ. Nítorí náà Eleasari ati Itamari ní ń ṣe iṣẹ́ alufaa ní ìgbà ayé Aaroni, baba wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nadabu ati Abihu si kú niwaju OLUWA, nigbati nwọn rubọ iná àjeji niwaju OLUWA ni ijù Sinai, nwọn kò si lí ọmọ: ati Eleasari ati Itamari nṣe iṣẹ alufa niwaju Aaroni baba wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Nádábù àti Ábíhù ti kú níwájú OLÚWA nígbà tí wọ́n rú iná àjèjì níwájú OLÚWA nínú ijù Sínáì, àwọn méjèèjì kò sì ní ọmọ. Báyìí Élíásárì àti Ítamárì ló sisẹ́ àlùfáà nígbà ayé Árónì baba wọn.