Numbers 3:43 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àkọ́bí ọkunrin, gẹ́gẹ́ bí orúkọ wọn, lati ọmọ oṣù kan lọ sókè ní iye wọn, lápapọ̀, wọn jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé igba ati mẹtalelaadọrin (22,273).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gbogbo awọn akọ́bi ọkunrin nipa iye orukọ, lati ọmọ oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ ninu eyiti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mọkanla o le ọrinlugba o din meje.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àpapọ̀ iye àwọn àkọ́bí ọkùnrin láti ọmọ oṣù kan ó lé, ní àkọsílẹ̀ orúkọ wọn jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlá ó lé ọ̀rìnlúgba ó dín méje (22,273).