Numbers 3:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Lefi yóo máa ṣe ìtọ́jú gbogbo ohun èlò Àgọ́ Àjọ, wọn óo sì máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún gbogbo ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ níbi mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki nwọn ki o si ma pa gbogbo ohun-èlo agọ́ ajọ mọ́, ati aṣẹ awọn ọmọ Israeli, lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò máa tọ́jú gbogbo ohun èlò inú Àgọ́ Ìpàdé, wọn yóò sì máa ṣe ojúṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ṣíṣe iṣẹ́ nínú àgọ́.