Numbers 30:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ kò bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ní ọjọ́ tí ó gbọ́, ó níláti san gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ nítorí pé ọkọ rẹ̀ kò lòdì sí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i patapata lati ọjọ́ dé ọjọ́; njẹ o fi mu gbogbo ẹjẹ́ rẹ̀ duro, tabi gbogbo ìde rẹ̀ ti mbẹ lara rẹ̀; o mu wọn duro, nitoriti o pa ẹnu rẹ̀ mọ si i li ọjọ́ na ti o gbọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ kò bá sọ nǹkan kan sí í nípa rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́, nígbà náà ni ó se ìwádí nípa ẹ̀jẹ́ àti ìbúra ìdè tí ó dè é. Kí ọkùnrin náà se ìwádìí lórí rẹ̀ láì sọ nípa rẹ̀ si nígbà tí ó gbọ́ nípa rẹ̀.