Numbers 31:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n kó wọn wá sọ́dọ̀ Mose ati Eleasari ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, ní òdìkejì odò Jọdani, lẹ́bàá Jẹriko.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si kó igbẹsin, ati ohun-iní, ati ikogun na wá sọdọ Mose, ati Eleasari alufa, ati sọdọ ijọ awọn ọmọ Israeli, si ibudó ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, ti mbẹ lẹba Jordani leti Jeriko.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí wọ́n bàjẹ́ àti ènìyàn àti ẹran wá sọ́dọ̀ Mósè àti Élíásárì àlùfáà, àti sọ́dọ̀ ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ibùdó àgọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì létí Jẹ́ríkò.