Numbers 31:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
àní, gbogbo ohun tí kò bá ti lè jóná ni a óo mú la iná kọjá, kí á lè sọ wọ́n di mímọ́; a óo sì fi omi ìwẹ̀nùmọ́ fọ àwọn ohun èlò tí wọn bá lè jóná.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo ohun ti o le kọja ninu iná, ni ki ẹnyin ki o mu là iná já yio si di mimọ́; ṣugbọn a o fi omi ìyasapakan wẹ̀ ẹ mọ́: ati gbogbo ohun ti kò le kọja ninu iná ni ki a mu là inu omi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohunkóhun tí ó lè la iná ni kí ẹ̀yin ó mú la iná, nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n ẹ ó ò fi omi ìyàsímímọ́ sọ ọ́ di mímọ́. Àti gbogbo ohun tí kò lè la iná kọjá ni kí a mú la inú omi.