Numbers 31:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lára ìdajì tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Israẹli, mú ẹyọ kan ninu araadọta ninu eniyan ati mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ẹran ọ̀sìn; kí o sì kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi tí ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ninu àbọ ti iṣe ti awọn ọmọ Israeli, ki iwọ ki o si gbà ipín kan ninu ãdọta, ninu enia, ninu malu, ninu kẹtẹkẹtẹ, ati ninu agbo-ẹran, ninu onirũru ẹran, ki o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi, ti nṣe itọju agọ́ OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lára ààbọ̀ ti Ísírẹ́lì, yan ọ̀kan kúrò nínú àádọ́ta, (50) yálà ènìyàn, ẹran ọ̀sìn, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, ewúrẹ́ tàbí ẹ̀yà ẹranko mìíràn. Kó wọn fún àwọn Léfì, tí ó dúró fún olùtọ́jú àgọ́ OLÚWA.”