Numbers 31:47 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ninu wọn, Mose mú ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu araadọta ninu àwọn eniyan ati ẹranko, ó sì kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi tí ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ OLUWA, bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ani ninu àbọ ti awọn ọmọ Israeli, Mose mú ipín kan ninu ãdọta, ati ti enia ati ti ẹran, o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi, ti nṣe itọju agọ́ OLUWA; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lára ààbọ̀ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Mósè yan ọ̀kan lára àádọ́ta (50) ènìyàn àti ẹranko gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pa á láṣẹ fún un. Ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì, tí ń ṣe olùtọ́jú àgọ́ OLÚWA.