Numbers 31:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà láàrin ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọmọ Israẹli, ẹgbaafa (12,000) ọkunrin ni wọ́n dájọ láti lọ sójú ogun, ẹgbẹẹgbẹrun láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni nwọn si yàn ninu awọn ẹgbẹgbẹrun enia Israeli, ẹgbẹrun enia ninu ẹ̀ya kọkan, ẹgba mẹfa enia ti o hamọra ogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yan nínú àwọn ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹgbẹ̀rún (1000) ènìyan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ènìyàn tí ó wọ ìhámọ́ra ogun.