Numbers 31:50 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà a mú ọrẹ ẹbọ: ohun ọ̀ṣọ́ wúrà, ẹ̀wọ̀n, ẹ̀gbà ọwọ́, òrùka, yẹtí, ati ìlẹ̀kẹ̀ wá fún OLUWA lára ìkógun wa, láti fi ṣe ẹbọ ètùtù fún wa níwájú OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina li awa ṣe mú ọrẹ-ebọ wá fun OLUWA, ohunkohun ti olukuluku ri, ohun ọ̀ṣọ wurà, ẹ̀wọn, ati jufù, ati oruka-àmi, ati oruka-etí, ati ìlẹkẹ, lati fi ṣètutu fun ọkàn wa niwaju OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà làwa ṣe mú ọrẹ ẹbọ wá fún OLÚWA, gbogbo ọrẹ wíwà tí a ní, wúrà, ẹ̀wọ̀n, àti júfù, àti òrùka: àmi, àti òrùka etí, àti ìlẹ̀kẹ̀ láti fi ṣe ètùtù fún ọkàn an wa níwájú OLÚWA.”