Numbers 31:52 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìwọ̀n gbogbo ọrẹ ẹbọ tí àwọn olórí ogun náà mú wá jẹ́ ẹgbaajọ ó lé ẹẹdẹgbẹrin ó lé aadọta (16,750) ṣekeli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gbogbo wurà ẹbọ igbesọsoke ti nwọn múwa fun OLUWA, lati ọdọ awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati lati ọdọ awọn balogun ọrọrún, o jẹ́ ẹgba mẹjọ o le ẹdẹgbẹrin o le ãdọta ṣekeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo wúrà tí àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún mú wá fún Mósè àti Élíásárì, èyí tí ó jẹ́ ẹbọ ìgbésókè fún OLÚWA jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé àádọ́ta (16,750) ṣékélì.