Numbers 32:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nisinsinyii, ẹ̀yin ìran ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí dìde gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá yín láti mú kí inú bí OLUWA gidigidi sí Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si kiyesi i, ẹnyin dide ni ipò baba nyin, iran ẹ̀lẹṣẹ, lati mu ibinu gbigbona OLUWA pọ̀ si i si Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Níbí ni ẹ̀yin wà, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ̀yin dìde ní ipò bàbá yín, ẹ sì jẹ́ kí ìbínú gbígbóná OLÚWA ru sí Ísírẹ́lì.